ÌFÍHÀN (Introduction)

ÌFÍHÀN SÍ ÌTÚPALẸ̀ ÌYÈ KÉMÍKÀ

Ṣíṣe Kémístrì ní ìpín méjì pàtàkì: Ìtúpalẹ̀ dídàrà (Qualitative Analysis) àti Ìtúpalẹ̀ Ìyè ipò (Quantitative Analysis).

Ìtúpalẹ̀ dídàrà ń ṣàfihàn ọ̀nà tí a fi lè mọ ohun èlò tàbí àwọn àpọ̀ èròjà tó wà nínú àpẹẹrẹ kémíkà kan. Ìtúpalẹ̀ yìí ní ẹ̀ka méjì: Ìtúpalẹ̀ Kémíkà Àìníròkò (Inorganic Analysis) àti Ìtúpalẹ̀ Kémíkà Oníròkò (Organic Analysis).

Ìtúpalẹ̀ Ìyè ipò jẹ́ àtòkọ́ àwọn ìdánwò tí ó ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè mọ ìwọn tàbí ìdá eròjà tó wà nínú àpẹẹrẹ ohun èlò kan. Ó ń jẹ́ kí a lè mọ iye tó pọ̀ tàbí tó díẹ̀ nínú ohun èlò tó ń ṣe àyẹ̀wò.

Ní àfihàn, àwọn ọ̀nà ìṣirò nínú ìtúpalẹ̀ kémíkà pín sí méjì:

  1. Ìtúpalẹ̀ Iwuwo (Gravimetric Analysis) — tí ó dá lórí ìwọn ìwuwo tààrà.
  2. Ìtúpalẹ̀ Folumétíríkì tàbí Tíatimétíríkì (Volumetric/Titrimetric Analysis) — tí ó dá lórí ìwọn ìpọ̀nọ́ omi ìtójú (solution). Àwọn ọ̀nà yìí ní Taítiréṣan ásíídì -béèsì (Acid-Base Titration) àti àwọn ọ̀nà míì tí a kì yóò fi hàn níbí.
ÌTÚPALẸ̀ KÉMÍKÀ

Nínú ìwé ìmọ̀ yìí, a máa dojú kọ́ ọ̀nà folumétíríkì (volumetric method) nínú ìtúpalẹ̀ kémíkà.

Ìtúpalẹ̀ Folumétíríkì ni ìmúlò láti mọ ìṣàrò (concentration)    ojútùú kan nípa Taítiréṣan rẹ̀ pẹ̀lú ojútùú míì tí ìṣàrò rẹ̀ ti á mọ̀ dájú. Ẹ̀kọ́ yìí yóò ní àwọn ìgbésẹ̀ bíi ìwọ̀n, ìmúrà    ojútùú, àti Taítiréṣan gangan.

A ṣe àtúmọ̀ ẹ̀kọ́ yìí láti kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ bí a ṣe ń ṣe ìdánwò Taítiréṣan tó ní nkan ṣe pẹ̀lú ásíídì -béèsì, kí wọ́n lè mọ́ ọ̀nà Ìtúpalẹ̀ Ìyè ipò (Quantitative Volumetric Analysis).

Ṣáájú ìdánwò náà, a ó kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà iṣẹ́ yàrá òjòmíta, àwọn ìṣọ́ra tí a gbọ́dọ̀ ṣe nígbà Taítiréṣan ásíídì -béèsì, àti lílò àwọn irinṣẹ́ pàtàkì tí a fi ń ṣe ìtúpalẹ̀ folumétíríkì.

Akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò tún kọ́ nípa àwọn ìpín S.I. (Système International) tí ó kún fún:

  • Ìpín Iwuwo (mass unit)
  • Ìpín Iwọ̀n Omi (volume unit)
  • Ìpín Iye Mọ́là (molar mass unit)

Ẹ̀kọ́ yìí yóò fojú kọ́ ìdánwò àmúlò (practical experiments) nípa Taítiréṣan ásíídì -béèsì, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìtúpalẹ̀ Ìyè ipò, kí ó sì tọ́ka sí àwọn ìru Taítiréṣan, àṣàyàn àwọn àmi ìtọ́kasí (indicators) àti ìwọn pH.

Ní ìpẹ̀yà, ẹ̀kọ́ yìí yóò tún ṣàlàyé Taítiréṣan ásíídì -béèsì tí ó ní ìmúrà ojútùú, àti Taítiréṣan ojútùú yẹn pẹ̀lú omi ojútùú míì tí ìṣàrò jé èyi tá mọ̀ tàbí a ó mọ̀ dájú. Àwọn àpẹẹrẹ ìlò (applications) Taítiréṣan ásíídì -béèsì  ni yóò tún fi hàn, kí akẹ́kọ̀ọ́ lè lóye ìtóbi àti àǹfààní ásíídì -béèsì ìtúpalẹ̀ folumétíríkì nínú ìmọ̀ kémíkà.

 

Listen to introductory Audio

Scroll to top